OWÓ-ORÍ ỌJÀ : ÌPÍNLẸ̀ Ọ̀YỌ́ FẸ́ DARAPỌ̀ MỌ́ ẸJỌ́ TÍ ÌJỌBA ÌPÍNLẸ̀ RIVERS PE ÌJỌBA ÀPAPỌ̀.
Olatunde Ogunniran
#Ìròyìn Òmìnira
30th September, 2021
oluominirayoruba**********
Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti béèrè lọ́wọ́ ilé-ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn tí ó ń jókòó ní ìlú Port Harcourt ní Ìpínlẹ̀ Rivers fún ààyè ìpẹjọ́pọ̀ nínú ẹjọ́ tí ìjọba ìpínlẹ̀ Rivers pe Agbẹjọ́rò-àgbà fún orílẹ̀-èdè yìí ní ìbámu pẹ̀lú èròǹgbà ìpínlẹ̀ náà láti gba àkóso gbígba owó-orí ọjà (VAT) kúrò lọ́wọ́ ìjọba àpapọ̀.
Ìwé-ìpẹ̀jọ́ tí Agbẹjọ́rò-àgbà fún ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ọ̀jọ̀gbọ́n Oyèlọ́wọ̀ Oyewọ kọ ń pè fún àsẹ ilé ẹjọ́ náà láti gbààyè fún ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ láti darapọ̀ mọ́ ẹjọ́ tí ìpínlẹ̀ Rivers pè.
Nínú ìwé ẹ̀bẹ̀ ìdarapọ̀ mọ́ ìpẹ̀jọ́ náà, ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ń bèèrè fún àsẹ méjì, láti darapọ̀ mọ́ ìpẹ̀jọ́ gẹ́gẹ́ bí olùpẹ́jọ́ gẹ́gẹ́ bí ó ti hàn nínú ìwé ìpẹ̀jọ́ kòtẹ́milọ́rùn FHC/PH/CS/149/2020 àti ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn CA/PH/282/2021, àti èyíkéyìí tí ilé ẹjọ́ lè wòye pé ó bójúmu.
Gẹ́gẹ́ bí Agbẹjọ́rò-àgbà ti ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti sọ, ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ kò mọ̀ tẹ́lẹ̀ nípa ìpẹ̀jọ́ tó wà láàrin Agbẹjọ́rò-àgbà ti ìpínlẹ̀ Rivers àti àjọ tó ń gba owó-orí ọjà fún ìjọba àpapọ̀, èyí tí wọ́n gbé lọ sí ilé-ẹjọ́ gíga títí ìgbà tí ìdájọ́ fi wáyé.
Ohun mìíràn tí ìwé-ìpẹ̀jọ́ náà tún dá lé lórí ni pé kí ìdájọ́ ilé-ẹjọ́ kan ìpínlẹ́ Ọ̀yọ́ ní gbígba owó-orí ọjà gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn ìpínlẹ̀ ti ilé ẹjọ́ kékeré fi òté lé e láti máa gba owó-orí ọjà ní agbègbè wọn.
Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tún kọ ọ́ pé olùpẹ̀jọ́ (Agbẹjọ́rò-àgbà ti ìpińlẹ̀) ni asojú fún ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ẹni tí èròǹgbà rẹ̀ láti máa gba owó-orí ọjà yó di mímúṣẹ ní ọ̀nà kan tàbí òmíràn nípaṣẹ̀ ẹjọ́ tí ilé-ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn bá gbé kalẹ̀.
Àgbékalẹ̀ ìpẹ̀jọ́ tí ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ bèèrè fún tún ni pé: ‘’Olùpẹ̀jọ́ jẹ́ alápẹjọ́pọ̀ tó ṣe kókó sí ẹjọ́ tí ó wà nílẹ̀ tí ó sì jẹ́ olùpẹ̀jọ́ tí yó mú àsẹ ìdájọ́ tí ilé-ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn bá gbé kalẹ̀ ṣẹ lórí ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn yìí.
‘’Èròǹgbà Abẹ̀bẹ̀-darapọ̀-mọ́ ẹjọ́ àti olùpẹ̀jọ́ papọ̀ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti jọ jẹ́ ìpínlẹ̀ nínú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.’’
Nínú ìwé-ìpè olójú ewé méjìlàá láti darapọ̀ mọ́ ẹ̀sùn, èyí tí Adarí ẹ̀sùn tó níí ṣe pẹ̀lú ará ìlú ní ilé ìgbìmọ̀ asòfin kọ.
Agbẹjọ́rò-àgbà àti Kọmísánnà fún ètò ìdájọ́, Àjọ tó ń sàkóso ètò ìdájọ́ ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ọlátújí Sunday Thomas, ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ wípé ní ìbámu pẹ̀lú ètò ìdájọ́ ní ilé-ẹjọ́ ṣe tẹ́wọ́ gba ìwé ẹ̀bẹ̀ náà, lérò pé ìpawọ́pọ̀ ṣẹ́jọ́ náà kò ní ṣe àkóbá fún akọ̀wé-bẹ̀bẹ̀ fún ìdàpọ̀-ẹjọ́ àti olùpẹjọ́. Ó sọ pé, ìpínlẹ̀, èyí tí ó jẹ́ ọ̀kan lára ìpínlẹ̀ orílẹ̀-èdè Nàíjìríà, ni ẹjọ́ ilé-ẹjọ́ náà yó kàn gbọ̀ngbọ̀n, ó ní dídarapọ̀ mọ́ ẹjọ́ tí ìpínlẹ̀ Rivers ti pè saájú yìí yó ṣe ìrànwọ́ fún dídènà àpètúnpè ẹjọ́ kan soso tí àwọn ìpínlẹ̀ lè pe ìjọba àpapọ̀.
Nínú ìwé ìpẹjọ́ ti ẹjọ́ tí ó wà nílẹ̀ níwájú ilé-ẹjọ́, ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ sọ pé ó dúró lórí ẹ̀sùn mẹ́jọ, ó sì kéde pé ìpínlẹ̀ náà jẹ́ ara ìpínlẹ̀ tó ṣe pàtàkì láti darapọ̀ nítorí ó ní ìfẹ́ sí àbájáde ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn náà.
Ìpínlẹ̀ náà tún fi lélẹ̀ pé lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti wọ́n ti tẹ̀lé gbogbo òfin àlàkalẹ̀ tán, ilé-ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn yó ríi pé ìwé-ẹ̀bẹ̀ náà ṣe pàtàkì, èyí tí ó wà ní ìbámu pẹ̀lú ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn gẹ́gẹ́ bí ìpínlẹ̀ ní orílẹ̀-èdè.
Ó sàpẹẹrẹ lọ́pọ̀lọpọ̀ láti inú àwọn ìwé òfin, ó sì parí pẹ̀lú u: ‘’A bẹ ilé-ẹjọ́ láti wá ojútùú sí kókó ohun tí a béèrè fún nínú ìwé ìpẹjọ́ yìí ní ìbámu pẹ̀lú èròǹgbà olùkọ̀wé bèèrè ààyè kí wọ́n sì rí pé kíkọ̀wé bèèrè ààyè ìdarapọ̀ náà tọ̀nà fún ìpínlẹ̀ tí ó fẹ́ láti darapọ̀ mọ́ ẹjọ́ Kọ̀tẹ́milọ́rùn yìí...
‘’Ní ìparí, a bẹ adájọ́ ilé-ẹjọ́ yìí láti gbààyè fún ìwé ìbéèrè fún ààyè ìdàpọ̀ yìí ní ìbámu pẹ̀lú ètò ìdájọ́ àti ìlànà ètò ìdájọ́ tó péye ní gbígbọ́ ẹjọ́ tí ó wà níwájú ilé-ẹjọ́ yìí
- Kategorie:
- Kunst & Kultur
- Keine Kommentare