KÒ ṢẸLẸ̀ RÍ : TAANI YÓ DI OLÚBÀDÀN TITUN? AWUYEWUYE BẸ́YỌ LẸ́YÌN ÌPAPÒDÀ ỌBA SALIU - Ọlátúndé Ògúnníran

KÒ ṢẸLẸ̀ RÍ : TAANI YÓ DI OLÚBÀDÀN TITUN? AWUYEWUYE BẸ́YỌ LẸ́YÌN ÌPAPÒDÀ ỌBA SALIU   - Ọlátúndé Ògúnníran


#Ìròyìn Òmìnira
3rd January, 2022
oluominirayoruba**********

Kìí ṣe àhesọ ọ̀rọ̀ mọ́ pé Olúbàdàn ti ilẹ̀ Ìbàdàn, Ọba Saliu Akanmu Adetunji Ajé Ogúgúlùsọ̀ I ti tẹ́rígbasọ. Ìsẹ̀lẹ̀ yí sẹlẹ̀ ní ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ kejì, oṣù Sẹ́rẹ́ (January), ọdún 2022 ní ilé ẹ̀kọ́sẹ́ ìsègùn (UCH), Ìbàdàn ní ẹni ọdún mẹ́tàléláàdọ́rùn-ún. Ọba Soliu Adetunji ni ó gorí ìtẹ́ ní ọjọ́ kẹrin oṣù Erénà (March), 2016 lẹ́yìn tí ọba Samuel Odugadé Odùlànà wàjà.
Ní àsìkò ìsàkóso rẹ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ awuyewuye ni ó sẹlẹ̀; pàápàá jùlọ nígbà tí aáwọ̀ kan bẹ́ sílẹ̀ láàrin Ọba Saliu Adetunji àti Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, olóògbé Abiọlá Ajímọ̀bi èyí tó mú Gómìnà gbé adé lé àwọn olóyè àgbà Ìbàdàn mọ́kànlélógún lórí. Ìgbésẹ̀ yí ni Gómìnà Sèyí Mákindé fagilé ní kété tó gba ọ̀pá àsẹ gẹ́gẹ́ bí i gómìnà titun ní ọdún 2019. Gbígbé adé fún àwọn àgbà olóyè yìí fa gbodónrósọ láàrin ọba Soliu Adetunji àti àwọn àgbà ìjòyè kan bí i Olóyè Lekan Balógun tí i ṣe òtún Olúbàdàn, Olóyè Owólabí Ọlákùlẹ́hìn tí i ṣe Balógun Ìbàdàn àti àwọn ìjòyè mìíràn. Aáwọ̀ yìí ló fa bí Olúbàdàn, Ọba Saliu Adetunji ṣe fi òfin de àwọn àgbà ìjòyè wọ̀nyí ní ààfin tí ó sì rọ̀ wọ́n lóyè fún ìgbà kan.
Ní báyìí tí ọba ti wàjà láì gbẹ́sẹ̀ kúrò lórí òfin tó fi de àwọn ìjòyè yìí, ǹjẹ́ wọ́n ha lẹ́tọ̀ọ́ láti dé ipò ọba bí gẹ́gẹ́ bí ó ti hàn lórí tábìlì orúkọ àwọn olóyè tí ọba tọ́ sí ní ti ipò wọn? Ìbéèrè yìí ló gún akọ̀ròyìn Ìròyìn Òmìnira ní kẹ́ṣẹ́.
Ìwòye àwọn ènìyàn ni pé; bí àwọn afọbajẹ bá tẹ̀lé ìlànà ìgbà ìwásẹ̀ ní yíyan ọba, a jẹ́ pé olóyè Lekan Balogun ni ọbá tọ́ sí, èyí yó sì jásí pé wọ́n tẹ òfin ọba lójú. Wọ́n tún wòye pé bí wọ́n bá pa òfin ọba mọ́, èyí túmọ̀ sí pé èyíkéyìí nínú olóyè Lekan Balogun àti àtẹlé rẹ̀ nínú tábìlì ipò oyè, olóyè Owolabí Ọlákùlẹ́hìn yó pàdánù ipò ọba tí yó sì fò wọ́n ru bọ́ sórí olóyè Rashidi Adewọlú Ládọjà, ẹni tí ó ti fi ìgbà kan rí jẹ́ gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tí ó sì tún jẹ́ baba ìsàlẹ̀ fún Gómìnà Seyi Mákindé.
Ìhà wo ni àwọn afọbajẹ yóó fì sí lórí ọ̀rọ̀ yí? Ṣé oyè ọba Ìbàdàn tí kìí ní awuyewuye láti ìgbà ìwáṣẹ̀ kò níí fa lọgbọlọgbọ báyìí?
Ṣùgbọ́n sá, àwọn ọjà ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ yóó wà ní títìpa ní ọjọ́ Ajé Mọ́ńdè, ọjọ́ kẹta oṣù Sẹ́rẹ́, láti bu ọlá fún Olúbàdàn tó wàjà. Gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde tó wá láti ọ̀dọ̀ Bàbálọ́jà ti Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Asíwájú Yẹkini Abass, tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí YK Abass, ti sọ léyìn ìpàdé pàjáwìrì tí àwọn olùdarí ọjà ṣe ní ọjọ́ Àìkú. Olóyè Abass sọ pé àwọn ṣe ìpinnu náà láti fi bu ọlá fún ọba náà látàrí ipa mánigbàgbé tó kó lórí ìdàgbàsókè ìlú Ìbàdàn.
Ọlátúndé Ògúnníran
Ìròyìn Òmìnira

Category:
Arts & Culture