OLÚBÀDÀN DARA PỌ̀ MỌ́ ÀWỌN BABA RẸ̀

OLÚBÀDÀN DARA PỌ̀ MỌ́ ÀWỌN BABA RẸ̀


#Ìròyìn Òmìnira
2nd January, 2022
oluominirayoruba**********

Ọlátúndé Ògúnníran


OLÚBÀDÀN DARÁ ILẸ̀!

Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ òní ni ìròyìn gba òde kan pé, Ọba Saliu Adetunji Ajeogúngúnnísọ̀ I tíí ṣe Olúbàdàn ti ilẹ̀ Ìbàdàn jáde láyé.

Gẹ́gẹ́ bí akọ̀ròyìn Òmìnira Yorùbá ti ríi gbọ́, ọjọ́ kejì oṣù kìn-ín-ní ọdún 2022 ni ọba náà jáde láyé ní ẹni ọdún mẹ́tàléláàdọ́rùn-ún ní ilé ẹ̀kọ́sẹ́ ìsègùn UCH, Ìbàdàn ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.
Nígbà tí oníròyìn wa kàn sí ọ̀kan lára àwọn àgbààgbà olóyè ìlú Ìbàdàn, wọ́n fi ìdí ìròyìn náà múlẹ̀ àti pé ara olóògbé náà ni wọ́n ti gbé lọ sí àafin ọba tó wà ní Pópóyemọja ní ìlú Ìbàdàn.

Ní ǹǹkan bí agogo mọ́kànlá òwúrọ̀ yìí ni wọ́n gbé ara Ọba Saliu Adetunji Aje Ògúngúnnísọ̀ wọ ààfin ní Pópóyemọja ní Ìbàdàn.
Ọba Saliu Adetunji ni ó jẹ Olúbàdàn ní ọjọ́ kẹrin oṣù Erénà (March), 2016 gẹ́gẹ́ bí Olúbàdàn kọkànlélógójì.

Ní báyìí, Àgbáríjọpọ̀ ẹgbẹ́ ọmọ Ìbàdàn (CCII) ti wá bá gbogbo ẹbí àti ọmọ Ìbàdàn kẹ́dùn ìpapòdà ọba Adetunji Ajeogúngúnnisọ̀ I. Ààrẹ gbogboogbò fún ẹgbẹ́ yìí, Ọmọọba Olúyẹ́misí Adéàga, ní orúkọ ẹgbẹ́ fi ètò ìlànà itẹ́ ẹ̀yẹ ìkẹyìn fú ọba tó wàjà náà síta; èyí tí ó wáyé ní gbọ̀ngàn Màpó ní aago kan àbọ̀ ọ̀ṣán òní.
Ìròyìn Òmìnira yóò máa fi tó wa létí bí gbogbo nǹkan bá ṣe ń lọ

Category:
Arts & Culture