YORÙBÁ SÙN WỌ́N FI HAUSA SE ỌDẸ, EWU Ń BẸ LÓKO LÓŃGẸ́. -HON.Ọ̀PÁLẸ́YẸ GBẸ́NGA

YORÙBÁ SÙN WỌ́N FI HAUSA SE ỌDẸ, EWU Ń BẸ LÓKO LÓŃGẸ́. -HON.Ọ̀PÁLẸ́YẸ GBẸ́NGA

FỌ̀RỌ̀WÁNILẸNUWÒ PẸ̀LÚ ỌNỌRÉBÙ Ọ̀PÁLẸ́YẸ GBÉNGA
Ọnọrébù Gbénga Ọ̀pálẹ́yẹ nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan tí ó wáyé lórí ètò ‘Ojúmọ́ ti mọ́’ èyí tí ilé iṣẹ́ Móhùnmáwòrán Oodu Tv Network gbé jáde ni ọjọ́ Àbámẹ́ta 13/3/2021. Nígbà tí ó ń dáhùn ìbéèrè lọ́kan-ò-jọ̀-kan tí atọ́kùn ètò, Olú Ayégbókìkí ń taari sí iwájú rẹ lórí ìsàkóso ìjọba APC tó wa nípò lọ́wọ́lọ́wọ́ ní orílẹ̀-èdè Nàíjíríà. Ọ̀pálẹ́yẹ ní ó hàn gbangba pé ètò ìsàkóso náà kò mọ́yán lórí tó nítorí pé eku kò ké bí eku, bẹ́ẹ̀ ni ẹyẹ kò ké bí ẹyẹ. Ó wòye pé ipò tí ètò ààbò wà lórílẹ̀-èdè yìí fi hàn pé ewu ń bẹ lóko Lóńgẹ; ó ní ńse ló dàbí ẹni pé apá àwọn elétò àbò kò fẹ́ ká ọ̀ràn náà mọ́, ó wá wòye pé pé i1nira ará ìlú ni oríire fáwọn kan. Ó bu ẹnu àtẹ́ lu ọ̀pọ̀ àwọn olósèlú tí wọn kò náání àwọn ará ìlú, tí wọ́n yàn láti kówó ìlú sápò ara tiwọn nìkan ju kí wọ́n ṣe ohun tó tọ́ fún ìlú lọ.

Ọnọrébù Ọ̀pálẹ́yẹ sàlàyé pé ìjínigbé tó kárí ilé-kárí-oko kò sẹ̀yìn àwọn ajẹgúdú-jẹrá olósèlú, ó ní àwọn náà kò ní ìbàlẹ̀ ọkàn mọ́ nítorí pé ọwọ́jà ìjínigbé náà ti ń kàn wọ́n pẹ̀lú. Nípa bí àwọn elétò àbò se máa ń polongo pé àwọn ti sẹ́ ogun áwọn Boko-haram ní àwọn agbègbè kan tí ó tún jẹ́ pé wọ́n á tún sẹ́yọ ní agbègbè náà; Ọ̀pálẹ́yẹ ní àwọn adarí wa ti sọ orílẹ̀-èdè Nàíjíríà di ayò tí wọ́n ta láàrin ara wọn. Ó ní bí ètò ààbò bá gbópọn, yóó nira fún àwọn ẹni-ibi yìí láti kó ọmọ bíi ọ̀ọ́dúnrún sáálọ àti pé bí ìjọba kò bá dáwọn mọ̀, kò níí máa bá wọn dúnàá-dúrà kó sì máa fi owó ìràpadà bẹ̀ wọ́n. Ó tẹ̀ síwájú láti sọ pé, ọ̀pọ̀ àwọn olósèlú ni kò lé orúkọ rere mọ́ àfi wúrà àti fàdákà. Ó tẹnu mọ́ọ pé ipò ló wu ọ̀pọ̀ olósèlú kìí se isẹ́ tí wọ́n ń lọ se bí wọ́n bá dé ipò. Ó ní èyí gan-an ni okùnfà asemọ́se gbogbo olósèlú tó di ipò mú títí dé orí àwọn gómìnà gbogbo. Ó ní ètò àbò ti mẹ́hẹ púpọ̀ àti pé ọ̀pọ̀ àwọn tí ó ń fi alùpùpù sisẹ́ ni wọ́n jẹ́ irinsẹ́ Boko-Haram.

Nínú àlàyé rẹ̀, Ọ̀pálẹ́yẹ ní àwọn Hausa kọ́ ni Boko-Haram bí kò se àwọn ẹ̀yà ará Chad tí ìwà wọn jọ ti Hausa. Ó gba gbogbo ará ìlú ní ìmọ̀ràn láti jẹ́ ojúlalákàn fi ń sọ́rí nípa kíkíyèsára lórí ààbò. Ó ní bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ gba ọdẹ fún sísọ́ ilé rẹ̀, ó gbọ́dọ̀ gba àdírẹ́ẹ́sì rẹ̀ kí ó sì wádìí rẹ̀ dájú; kí á má baà di ìjẹ fún wọn. Ó se àpẹẹrẹ àwọn agbègbè tí àwọn ẹni-ibi yìí pọ̀ sí ní igboro Ìbàdàn, bí i: Olúyọ̀lé, Mobil (Ring-Road), Bódìjà, NNPC, Àpáta, Ilé Ògúndoyin ní Ring-Road àti Agbájé ní New-Garage.

Ọnọrébù Ọ̀pálẹ́yẹ Gbénga gba àwọn alásẹ níyànjú láti má fi ti ẹgbẹ́ òsèlú se bí wọ́n bá fẹ́ sàseyọrí ṣùgbọ́n kí wọ́n se àmúlò ẹnikẹ́ni tí ó bá kójú òṣùnwọ̀n láì fi ti ẹgbẹ́ òsèlú se. Ọ̀pálẹ́yẹ gba ìjọba ní ìmọ̀ràn láti ríi pé gbogbo àwọn ọdẹ asọ́lé ló gba ìwé ìdánimọ̀ lábẹ́ ilé-isẹ́ ẹ̀sọ́ aláàbò aráàlú (Civil Defence)

Nígbà tí ó ń dáhùn ìbéèrè lórí ìgbésẹ̀ ìjára-ẹni-gbà lọ́wọ́ àwọn ẹni-ibi lòdì sí àlàkálẹ̀ ìgbésẹ̀ ìjọba, Ọnọrébù ní kò bá òfin orílẹ̀-èdè yìí mu láti mú òfin lọ́wọ́ ara ẹni, ó ní ṣùgbọ́n bí ìjọba kò bá wá ojútùú sí ọ̀rọ̀ náà, àwọń ará ìlú yóò wá ọ̀nà àbáyọ fúnra wọn. Ó ní bí ìjọba bá kọ̀ láti se ojúse rẹ̀ bó ti tọ́, àwọn ará ìlú yóò wá ọ̀nà láti gba ara wọn là.

O tún sọ̀rọ̀ lórí àìnífẹ̀ẹ́ tó jọba láàrin àwọn ẹ̀yà Yorùbá; ó ní èyí gan-an ni ó máa ń fi ìyà jẹ wọ́n. Ó sàlàyé pé àwọn Yorùbá tó wà lókè kìí náání àwọn ènìyàn wọn, èyí tí kò sì rí bẹ́ẹ̀ láàrin àwọn ẹ̀yà Hausa.

Nígbà tí ó ń dáhùn ìbéèrè lórí ipò tí Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ mú nínú ètò ìsèjọba rẹ̀. Ọnọrébù ní òhun yóò gbe sórí òsùwọ̀n gẹ́gẹ́ bí ará ìlú dípò bí òsèlú. Ó ní Gómìnà kò tíì se é gbé sórí òsùnwọ̀n báyìí nítorí pé ó sì sẹ̀sẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni, ṣùgbọ́n ó gbà á ní ìmọ̀ràn láti se àtúnse lórí ètò àbò kí ó lè gbópọn sí i nítorí pé ó ti mẹ́hẹ púpọ̀. Ọ̀pálẹ́yẹ tún sọ ọ́ síwájú sí i pé kí Gómìnà wá ojúse kan gbòógì fún àwọn ọmọ ìsọta nítorí ọwọ́ tó bá dilẹ̀ lèṣù ń bẹ̀ níṣẹ́ àti pé olè níí mẹṣẹ̀ olè tọ̀ lórí àpáta. Ó tún gba àwọn amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ Gómìnà lámọ̀ràn láti má a sọ ohun tí ó yẹ dípò ohun tí Gómìnà ń fẹ́ láti gbọ́.

Nípa ti ìpàdé àpérò láì fi ẹgbẹ́ òsèlú se, Ọnọrébù Ọ̀pálẹ́yẹ Gbénga tẹnu mọ́ọ pé ìgbésẹ̀ yìí dára púpọ̀, ó sì lè se ìrànwọ́ fún ìlọsíwájú ìlú.

Ó wòye pé ọ̀rọ̀ ìbò ọdún 2023 kìí se ohun tí a lè máa sọ báyìí, nítorí nǹkan kò fara rọ lórílẹ̀ èdè yìí. Ó ní ẹni tí ó bá ń polongo ìbò lásìkò yìí kò ní àròjilẹ̀. Ó ní bí ìjọba kò bá wá ọ̀nà àbáyọ sí ìsòro ìlú báyìí, ó lè fa ohun tí kò dára kí ọdún 2023 tó wọlé dé.

Lórí ìbéèrè bí ìran Yorùbá ti se ń gbìrò láti pínyà pẹ̀lú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Ó sàlàyé pé kò sí ohun tó burú níbẹ̀, ṣùgbọ́n, ó ní ohun tó burú ni pé kí ènìyàn má mọ ohun tí ó fẹ́ se kí ó tó dáwọ́ lé e.

Category:
Public News 
Written by:
#Ìròyìn Òmìnira#, Ọlátúndé Ògúnníran
Donate now:

GTBank 0220925636