ÌPÈ SÍ ÀJỌ YORÙBÁ NATION GENERAL COUNCIL (ÌGBÌMÒ GBOGBOGBÒ) ÈKÍNÍ TI UNITED KINGDOM NÍ ỌJỌ́ ÌSINMI 21/3/21 NÍ ORÍ ZOOM NI AGOGO MÉJE ÌRỌ̀LẸ́.

ÌPÈ SÍ ÀJỌ YORÙBÁ NATION GENERAL COUNCIL (ÌGBÌMÒ GBOGBOGBÒ) ÈKÍNÍ TI UNITED KINGDOM NÍ ỌJỌ́ ÌSINMI 21/3/21 NÍ ORÍ ZOOM NI AGOGO MÉJE ÌRỌ̀LẸ́.

Mo kí gbogbo àwọn bàbá àti màmá wa ní ile àti ní òkè òkun pàápàá àwọn tí wọ́n wà ní orílẹ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì (United Kingdom). Ẹ kú iṣẹ́ takuntakun.

Mo kí gbogbo àwa ọmọ Yorùbá pátápátá. A kú ìmúra sílẹ̀ àti ìfi ojú sọ́nà orílẹ̀ èdè wa, Yorùbá Nation.

Mo kí gbogbo àwọn ajagun wá àti àwọn olórí ẹgbẹ́ gbogbo pàápàá àwọn sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ wa, àwa ni a máa rẹ́rín ni ìkẹyìn. Ẹ kú iṣẹ́ ìlú gbogbo ò.

Orúkọ mi ni Ọ̀túnba Mobọ́lají Fálàṣẹ.

Ìfilọ̀ ṣókí yí tí í ṣe ìpè sí ìpàdé ni mo ní fún gbogbo àwa ọmọ Yorùbá tí a wà ní UK lórí ìgbésẹ̀ rere fún ìtẹ̀síwájú gbogbo wa.

Gbogbo wa ni a mọ̀ wípé ó ti dé ojú ẹ̀ báyìí ní ilé. Ìròhìn tí à ń gbọ́ fi nyé wa wípé a ní láti gbé ìgbésẹ̀ ní kíákíá láti gba orílẹ̀ èdè wa là. Èyí nìkan ni ó ma fún wa ní gbogbo agbára òfin àti àṣẹ ìjọba láti ṣé ogun tí ó ń jà wá ni ilé. À kò lè wà lábẹ́ iná, ní orí òrùlé, láti já ìjà yí. A ní láti kọ́kọ́ jáde kúrò pátápátá ni. We cannot fight underneath this massive fire burning over our roof heads; we must get out fast!

A ti fi gbogbo ètò wọ̀nyí tó àwọn bàbá wa gbogbo ní ilé létí, pàápàá àwọn bàbá Akíntóyè, wọn sì ti fi àṣẹ si. A ṣe ìpàdé pẹ̀lú àwọn onirohin (Press Conference) àkọ́kọ́ ni ọjọ́ àlaàmísì Thursday 4/3/21 tí wọ́n wà níbẹ̀ pelu awon bàbà wá Victor Táíwò àti àwọn àgbàgbà wa míràn pẹ̀lú láti ṣí ètò náà. Wọn sọ fún wa wípé inú wọn dùn si wón fi ọwọ́ síi, wọ́n sì ní ki à tẹ̀ síwájú. Ìgbésẹ̀ yí ni ìtẹ̀síwájú ìṣẹ́ náà báyìí.

Nítorí náà ìgbìmọ̀ọ́ fì ’dí hẹ - Pro tem Project Council tí wọ́n ti n ṣe iṣẹ́ lábẹ́lẹ̀ - ti ṣe ètò fún gbogbo wa tí a wà ni UK láti ṣe ìfi lọ́lẹ̀:

 • - ìkíní General Council,
 • - ìkejì Central Office àti
 • - ìkẹ́ta yí yan Chief Officer (Asiwaju)

fún iṣẹ́ ati ìdarí gbogbo ètò Yorùbá Nation wá ní United Kingdom.

Pro tem Project Council yí tí ṣe àkójọ gbogbo ànfàní àti ìwúlò bíi méjì lé lọ́gbọ̀n tí ó ń dúró de Yorùbá tí a bá ní àkóso yí ni UK.

Ní ore ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, Èmi ni Chairman Pro tem Project Council tí à ńṣe iṣẹ̀ yìí fún Yorùbá Nation láti UK.

A ti ń bá àwọn ìsọ̀rí mẹ́ta wọ̀n yí sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ àpéjọ General Council ti UK yí, kí gbogbo wọn lè wá ní ìpàdé àkọ́kọ́ yìí, kí wọn sì bẹ̀rẹ̀ ìṣẹ́ ní kíákíá. Kò sí àsìkò mọ́, ijáfara l'éwu.

- Ìsọ̀rí kíní ni aṣojú àwọn ọmọ èdè gbogbo ní abẹ́ èdè Yorùbá tí wọ́n wà ni UK (sub-ethnic groups). Ní àṣẹ Ọlọ́run gbogbo wa máa yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun ní àìpẹ́ yi.

- Ìsọ̀rí kejì ni àwọn àgbàgbà ilẹ̀ Yorùbá tí wọ́n ti wà níwájú ogún yi tipẹ́, tí wọ́n ń gbé ní UK. Ẹ̀ẹ́ pẹ́ fún wa, kò ní rẹ̀ yín ò.

- Ìsọ̀rí keta ni àwọn adarí tàbí aṣojú gbogbo ẹgbẹ́ tí wọ́n wà nínú ìjà ǹgbara wa yìí ní UK. Gbogbo wá máa ṣe àṣeyọrí.

Gbogbo àwọn ìsọ̀rí mẹ́ta wọ̀nyí ni a ń pè sí ìpàdé ńlá yi ní ọjọ́ ìsinmi 21/3/21 ní agogo méje láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣepọ̀ wa ní UK. Tí a bá ní ogun a máa ní olórí ogun ni, tí a bá sì ní ìjọba a máa ní ọba, a ní ìmọ̀ àti Ọmọlúwàbí ìwà tó tọ́ láti kó ara wa jọ fún arawa. UK ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ yi, àá sì ṣe àṣeyọrí. Àmín.

Fún àwọn tí ó wà lábẹ́ ìsọ̀rí kiní a ti ṣe àwọn àkójọ wọ̀nyí. Ẹ jọ̀wọ́ tí e bá jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn èdè ilẹ̀ẹ́ wa wọ̀nyí tí ẹ sì ń gbé ní UK, à ń pè yín sí ìpàdé yi ní ọjọ́ ìsinmi 21/3/21 ki ẹ bá Yorùbá Nation UK pé láti ṣe ìpàdé yi. Tàbí tí e bá mọ àwọn aṣojú àwọn ọmọ èdè Yorùbá wọ̀nyí tí wọ́n ní ẹgbẹ́ ní UK ẹ jọ̀wọ́ kí ẹ bá wà sọ fún wọn tàbí kí ẹ sọ fún wa.

 1. Ibadan/Ibarapa
 2. Egba Egbado
 3. Ijebu/Remo
 4. Oyo
 5. Ekiti
 6. Ijesa land
 7. Ikale/Ilaje/Apoi
 8. Ife/Odigbo
 9. Igbomina/Ila
 10. Awori/Eko
 11. Itsekiri
 12. Egun/Sabe/Popo/Oyi – Benin Rep.
 13. Akoko
 14. Edo/Ibini
 15. Okun - Kogi
 16. Ondo/Akure/Owo/Ileoluji
 17. Ilorin/Ibolo/Ofa
 18. Àti gbogbo ọmọ èdè tí í ṣe ti Yorùbá tí a kò bá dárúkọ, gbogbo yín ni Yorùbá Nation ńpè wípé kí ẹ wá.

Ìṣẹ́ àti ìgbésẹ̀ ti lọ gan-an lórí bí ati ṣe máa ṣe ètò ara wa fún ìtẹ̀síwájú orílẹ̀ èdè Yorùbá. Ìpàdé àkọ́kọ́ yìí ni a ti máa ṣe ètò gbogbo ní àgbájọ ọwọ́. Ẹ jẹ́ kí a sọ fún gbogbo ọmọ Yorùbá tí wọ́n ń gbé ní United Kingdom wípé ìjọba Yorùbá ti dé tán, e má jẹ́ kí wọ́n fi yín sílẹ̀ sẹhìn lọ, nítorí a kò fẹ́ fi ẹnikẹ́ni sílẹ̀ sẹ́hìn rárá rárá.

Ọwọ́ wa ni ìjọba wá wà. Àwa ni a máa gbé ìgbésẹ̀ ìgbàlà wa kò sí ẹni tí ó ma gbé e fún wa. Àsìkò ọ̀rọ̀ púpọ̀ ti ń kọjá báyìí, àsìkò ìgbésẹ̀ iṣẹ́ gidigidi ni ó ti dé bá wa báyìí. A kú iṣẹ́ takúntakún ò.

Ní àṣẹ Ọlọ́run àti àwọn alálẹ̀ Yorùbá, ohun tí a kò rò kò ni bá ohun rere tí a ń rò jẹ́. Àṣẹ, Èdùmàrè.

Á júṣe fún wa o.

Ní ẹ̀kàn si ọjọ́ ìpàdé àkọ́kọ́ ìgbìmọ̀ gbogbogbò (General Council) Yorùbá Nation ti UK yíò wáyé ni ọjọ́ ìsinmi 21/3/21 ní agogo méje ìrọ̀lẹ́ - 7pm ni oríi ZOOM.

Tí ẹnikẹ́ni bá ní ìbéèrè tàbí ó ń fẹ́ ìtọ́nisọ́naà ẹ jọ̀wọ́ kí ẹ kọ àtẹ̀ránṣẹ̀, tàbí kí ẹ pe number wọ̀nyí –

07799127851 tàbí 07950485792

Ẹ ṣeun púpọ̀.

Ọ̀túnba Arc Mobọ́lájí Fálàṣẹ

Chairman

Pro tem Project Council

Category:
Public News