ẸGBẸ́ AKÉWÌ PARAPỌ̀ LÁGBÀÁYÉ

ẸGBẸ́ AKÉWÌ PARAPỌ̀ LÁGBÀÁYÉ

•••••AKÉWÌ PARAPỌ̀•••••••

: Ẹgbẹ́ Akéwì Parapọ̀ Lágbàáyé

Akéwì parapọ̀,
Alárògún ni wá.
Imú ló ni kánbó,
Àgbọ̀n ìsàlẹ̀ ló ní họ́ọ́hùhọ́ọ́hù,
Ẹṣin ló ni eré sísá,
Olókìtí ọ̀bọ kò pé méjì,
Ẹranko wo ló tún tóbi tÉrin nígbó náà?
Kòsí ,ó dayé àtúnwá.

Akéwì parapọ̀,
Alárògún ni wá.
Àwa la lọ̀rọ̀,
Àwa la làṣà
Àwa la nìṣe,
Àwa la lèdè,
Àwa lelédè tó mèdè,
Àwa là ń pèdè tó peregedé láwùjọ pèdèpèdè,
Télédè ń mú nínú èdè wa fi pèdè.

Akéwì parapọ̀,
Alárògún ni wá.
Àì rìn pọ̀ ejò,
Òhun ní i jẹ ọmọ ejò níyà.
Bọ́ká bá ṣáájú,
Tí paramọ́lẹ̀ tẹ̀le,
Òjòlá lọ́wọ́ ọ̀tún,
Sèbé lọ́wọ́ òsì,
Baba taló tó bẹ́ẹ̀ láti ko ọmọ ejò lọ́nà?

Akéwì parapò,
Alárògún ni wá.
Ìṣọ̀kan ló jẹwá lógún,
Ìfọkàntán lagbádá wa,
Òtítọ inú làwọ̀tẹ́lẹ̀ wa,
Akínkanjú ni ṣòkòtò wa,
Iyì lAdé orí wa,
Ẹ̀yẹ lẹ̀ṣọ́ ọ̀run wa.
Bàbá ta ló sọ pé kò yẹ wá naa?
Bó bá wà,
Ìran afọ́jú ni baba tó bi lọ́mọ.
Ọgbọ́n ò pin síbi kan,
Òhun ló jẹ́ ká parapò.
Ìmọ̀ ò pin sílé ẹnìkan,
Òhun ló sọ wá dọmọ ìyá.
Ẹní mọ̀ yí,
Kò mọ tọ̀un,
Òhun ló sọ wá di kòrí-kòsùn,
Ìwà ọmọlúàbí ló jẹwá lógún.

Akéwì parapò,
Alárògún ni wá,
Ìfẹ́ òtítọ́ làmùrè wa.
Ká kéwì òtítọ́,
Láyé fí n pè wá lákéwì aṣòòtítọ́.
A gbó lẹ́nu bí ẹyẹ ajata,
A ṣoro kò lónà bi kìnìún olóòlàjù.

Bí Àṣà, Èdè àti Ìṣe Yorúbá kò ṣe ní bàjẹ́,
Òhun ló jẹ wá lógún.
Ká kìlọ̀ ìwà ìbàjẹ́ láwùjọ,
Òhun ni kàkàkí wa n fọn síta.
Ìwà ìrẹ̀lẹ̀ àti ọmọlúàbí bá gbilẹ̀ láwùjọ.
Akéwì wa ni láti sọ.

Akéwì parapọ̀,
Alárògún ni wá,
Òjíṣẹ́ Èdùmàrè ní wá.
Àwa lapèdè àrà télédè ń mú nínú èdè rẹ̀ fi pèdè tó peregedé ni gbàgéde èdè.

© Bámgbọ́pàá

© Ẹgbẹ́ Akéwì Parapọ̀ Lágbàáyé

Category:
Arts & Culture